Mark 2:18-22

Ìbéèrè nípa àwẹ̀ lọ́wọ́ Jesu

18 aÀwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu àti àwọn Farisi a máa gbààwẹ̀: Àwọn ènìyàn kan sì wá, wọ́n sì bi í pé, “Èéṣe tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Farisi fi ń gbààwẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ kò gbààwẹ̀?”

19Jesu dáhùn wí pé, “Báwo ni àwọn àlejò ọkọ ìyàwó yóò ṣe máa gbààwẹ̀ nígbà tí ọkọ ìyàwó ṣì wà lọ́dọ̀ wọn? 20 bṢùgbọ́n láìpẹ́ ọjọ́, a ó gba ọkọ ìyàwó kúrò lọ́dọ̀ wọn. Nígbà náà wọn yóò gbààwẹ̀ ni ọjọ́ wọ̀nyí.”

21 “Kò sí ẹni tí ń fi ìrépé aṣọ tuntun lẹ ògbólógbòó ẹ̀wù, bí ó ba ṣe bẹ́ẹ̀, èyí tuntun tí a fi lẹ̀ ẹ́ yóò fàya kúrò lára ògbólógbòó, yíya rẹ̀ yóò sí burú púpọ̀ jù. 22Kò sì sí ẹni tí ń fi ọtí wáìnì tuntun sínú ìgò wáìnì ògbólógbòó. Bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọtí wáìnì náà yóò fa ìgò náà ya, ọtí wáìnì a sì dàànù, bákan náà ni ìgò náà, ṣùgbọ́n ọtí wáìnì tuntun ni a n fi sínú ìgò wáìnì tuntun.”

Copyright information for YorBMYO